Monday, June 3, 2019

ORIKI IBADAN..

...


    Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi Oyesile Olugbode, Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo, Ilu Oluyedun baba Ibadan. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun. Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan. Labee Oba wa Kabiesi Saliu Akanmu Adetunji. Ibadan onii baje ooooooooo....Ibadan! omo ajorosun,omo agbosasamosa, omo agboyayamoya,igbo surusu oke gulutu igbo surusu ni baba wa fii bologun loju,ologun oni ko ere osabari koni ko ija,boba dijo ija ejeki aran se pe osabari,ewure dudu ni baba fibe ogun agbo dudu ni baba fibe ogun,marioo uno ko ogun-un ooo, ibadan ojigbin omo afi itoo  sewinbo, omo ajegbin yo fikarahun forimun,omo esin rogun jo arogun tola wan jo jagun ilu iwarun ni wan fi ida bole jagun ijaye,ibadan ara ogbojo dogbon yoke omo ike mi o joti oya emon gbemi fun oya igba kangunkangun mi kojo to osaa emon gbemi fo osaa lawe ike mi di ike amun seye omo ari ike yan gbongan-an  ojonla laromi we nile arolu omo ajorosun omo ori oroo je lojumon omo ogbadun... Ki emiola ogun kabiosi olorun oba ni kan ni,sugbon oba wa olubadan kope layeoo,ko gbogbogbo bi olu gbogbo tigbo laye,ki ogbogbogbo bi oba ni takura tigbo laye ooo, omo araye eba n sowipe ogunwan lagba opitan niju ki oba olubadan ti ile ibadan kopelaye koju tarayoku loo ogunwan lagba opitan niju,...

No comments:

Post a Comment